PHARMACY
ÒGUN PÀJÁWÌRÌ TÍ Ó Ń DÈNÀ OYÚN NÍNÍ
Akiyesi! Ti o ko ba ri nkan oṣu re laarin ọjọ meje ti o ti n reti rẹ,
lọ ri awọn eleto ilera rẹ kiakia fun ayẹwo ati itọni. O ṣe
ṣe ki o ti loyun.
Alaye kikun!
w Ẹ ma ṣe lo ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ju
ẹkan lọ laarin wakati mẹrin-le-logun, awọn ilana
ifetosọmọbibi miran wa ti o munadoko
w Maṣe bẹru tabi foya. Ti o ba n ni ibalopo leralera,
lilo ilana ifetosọmọbibi (ogun onikoro, alabẹrẹ,
oloju-ara ati onisana apa) jẹ ọna ti o munadoko lati
dena oyun
w Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní kii dabobo lọwọ
arun ibalopo bii Eedi.
Ti wahala ba wa?Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní kii fa inira ti o le. Nigba miran, o le fa inira pẹpẹpẹ bii ki eebi ma gbe ni ati ori fifọ. O si le fa ki nkan oṣu awọn obirin kọọkan ma ṣe segesege, ṣugbon gbogbo eyi ki i ṣe okunfa aisan si ni lara lọjọ iwaju bẹ si ni kii fa airọmọbi.
O dara lati lo ogun yi ni kete lẹyin ibalopo
lai lo idabobo kankan.
Modern Family Planning Methods: Safe and Trusted
Dena oyun nini lẹyin ti o ba ni ibalọpọ lai lo idabobo kankan
Nibo ni a ti le ri Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní?Ẹ le gba ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ni ile iwosan ijọba ati aladani (ile ita ogun)
Ẹ le gba ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní lai si iwe igba ogun.
Lo ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní bi o ti yẹ:
l Nigbati ilana idabobo ti a lo ba ja ni kulẹ tabi ti a ko lo bi o ṣe yẹ. Fun apẹrẹ, ti rọba idabobo ba bẹ tabi ti a ba gbagbe lati lo ogun onikoro lojojumọ
l Nigbati a ba fi ipa ba ni ni ibalopo
l Nigbati a ko ba lo ilana idabobo kankan
Nigbawo ati bawo ni a se n lo?Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní yíó ṣiṣe to munadoko níwọn igba ti a ba tete lo lẹyin ibalopo lai lo idabobo kankan. Sugbọn ogun yi o ni ṣiṣe ti a ba lo lẹyin ọjọ marun ti a ni ibalopo lai lo idabobo kankan.
Kíni ògùn yi?Ògun pàjáwìrì yi ń dènà oyún níní laarin ọgọfa wakati (ọjọ marun) lẹyin ibalopo lai lo idabobo kankan.
Gbogbo obirin ti o ti to bimo ni o le lo ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní lẹyin ìbálòpo lai lo ìdábòbò kankan.
Bawo lo ṣe n ṣiṣe?Ògun pàjáwìrì yi ma ń dènà oyún níní. Ko le ṣe ifarapa fun oyun ti o ti wa lara, bẹ si ni ki i nṣe oyun. Ko le ṣe idabobo fun ibalopo ti a ni lẹhin ti a ba ti lo ogun yii.
Ẹ ma ṣe lo ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ju ẹkan lọ laarin wakati mẹrin-le-logun.
Pẹlu iranlọwọ akọṣẹmọṣẹ ifetosọmọbibi, ẹ le yan ilana miran ti o fi ni lọkan balẹ ju ilana pajawiri lọ, fun apẹrẹ ogun onikoro, alabẹrẹ, oloju-ara, oniṣana apa ati bẹbẹlo.
Ti o ba nṣe iyemeji, lọ ri eleto ilera re
Ògun pàjáwìrì tí ó ń dènà oyún níní ki ṣe oun ti a le fi rọpo ilana ifetosọmọbibi.
Top Related