Itan nipa awon omo abiola 1

78

description

Itan nipa awon omo Abiola, Ile-Asalu, Iree, Osun State Nigeria.

Transcript of Itan nipa awon omo abiola 1

Page 1: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 2: Itan nipa awon omo abiola 1

ITAN NIPA AWON OMO ABIOLAILE ASALU, OKE-AREE, IREE, NIGERIA.

1.0 IPILESE ATI ORISUN AWON OMO ABIOLAKo si bi a ti le ko itan awon Omo Abiola ilu Iree lai so itan ile Asalu Iree ni soki nitoripe Ebi ninu ile Asalu Oluyeye ni Ilu Iree ni won je. Itan ti mo ko nipa awon omo Abiola bere ni bi irinwo odun sehin.Itan afenuso ti a banile so wipe ilu Oyo ni Onipee ti o je baba larooye ati Arolu ti lo si ilu Ipee (Kwara State) ati wipe ilu Ipee ni Larooye pelu Arolu ti wa te Ilu Iree do. Itan so wipe opolopo awon Omo Ile Asalu ni Ilu Iree lo wa lati Oyo ati Ipee lati wa ba awon ara Ile won ti o ti tedo si Iree.

Ni igba ogun Ile Yoruba, Baba awon Omo Abiola ti oruko re nje Olagunju Olohunde wa lati Oyo si Ibadan. Olohunde si ngbe Ayeye ni Ilu Ibadan. Ogun Yoruba bere si gori ogun, Olohunde kuro ni Ilu Ibadan, o si wa baa awon Ebi Baba re ni Ilu Iree. Awon ebi wonyi ni Larooye, Arolu ati awon yoku ti won wa si

Page 3: Itan nipa awon omo abiola 1

Iree lati Ipee. Ojo ngori ojo Olagunju Olohunde si di pakoyi onisowo ni Ilu Iree.

Lati fi idi itan atenuso yi mule, okan ninu awon Omo idi Olagunju Olohunde Ile Asalu Iree lo si Oyo lati darapo mo awon Omo Baba won gege bi Omo Oba ni Ilu Oyo, eleyi ni, Amusa Olatunji Adedeji ti inangije re nje “Adeoba”, Omo omo Olagunju Olohunde ti o je omo Adedeji, ti ise Omo Iya ati Baba Abiola Akande ati Akinola.

Amusa Olatunji lo si odo Oba Oyo, won pa itan, Oba ati Ijoye oyo si gba pe omo idile Oba Oyo nii se. Ila mejomejo ni Amusa Olatunji ko tele, sugbon Oba Oyo ati awon Ijoye Oyo si tun koo ni ila ni itan ati Apa gege bi Omo Oba.

Oriki ti Amusa Olatunji Adeoba mu pada si Ilu Iree nigba na ni:Omo Oba l’oyoOmo akiti olu

Page 4: Itan nipa awon omo abiola 1

Omo osupa le a ni o gunEniti owo Baba re ba too ko re tunse.

Amusa Olatunji ko ise ADE OBA sisin, o si se ise yi ni Ilu Ajilete idogo ati Alaari ki o to jade ni aye.ORIKI ILE ASALU

Omo Agan ko bi duduOmo Agan oran ti yan losanAkinoro Ole ko JobaBeni Ole ko ta giri sowo.

Gege bi itan, oruko ti ile yi nje tele ni Ile Olupini Oluyinu nigbati o se, nwon bere si pe ni Ile TENIOLA, nigbati o tun pe, nwon npe Ile yi ni Ile Asalu.

Awon enia Ile Asalu wa lati Ipee Kwara State, awon kan wa lati Ibadan beni awon kan si wa

Page 5: Itan nipa awon omo abiola 1

lati Offa-Kwara State. Awon EKA Ile Asalu je Odede meta bayi:

1. IDI OLAGUNJU OLOHUNDEa. ABIOLAb. AKINOLAc. ADEDEJId. ORISADARE LATI OYO/IBADAN e. AJAYIf. ATOYEBIg. TALE FANJANUh. LAWANI BEWAJI awon ni Omo abirin esin Kutupa-kutupa2. IDI OGUNGBADE ADIGUN OMO OLUYEYEa. OGUNTUNDEb. OGUNLOWOc. LANUMId. YESUFUe. OJELABI

Page 6: Itan nipa awon omo abiola 1

f. OGUNGBENLE LATI IPEE KWARAg. ABIALAh. OJEWUYIi. ASUNMOj. AJIBODU 3. IDI ADEOLA a. SOLOMON BABALOLAb. ADERIBIGBEc. ADEGBOYEd. OLANIYAN LATI OFFA IPINLE KWARA e. ADESINA

ORISA ASALUOro adayeba ni Ilu Iree lo bayi:

Page 7: Itan nipa awon omo abiola 1

“EESA LO NI ORISAOJOMU LO NI EEGUNASALU NI IGBAKEJI OBA”

ITANObinrin arewa kan ti oruko re nje ABENI lati Ilu Efon Alaaye je Olorisa ti o nma bo ORISALA.

Obinrin yi ma ngbe Orisa re wa si Ilu Iree ti o si ma nkiri Orisa na. bi o ba ti gbe Orisa yi ka, o ma nlu sekere lati polongo ORISALA yi fun t’omode t’agba ni ilU Iree. Awon Omode a si ma wo tele l’eyin. ile Oba Iree ni Obinrin yi ma de si ti o ba ti wa si ilu Iree.

Gbogbo Ilu Iree gba pe Orisala yi ma nfun awon aagan l’omo bibi. Orin ti won nma nko ni ojo ita orisa na ni yi:

Page 8: Itan nipa awon omo abiola 1

“OLOJO GBONGBON NBI - GBON BIORISA GBONGBON BI – GBON BIOLOJO K’OMODALE JUKULUJUKEOLOJO K’OMODALEMO HE!ORISA KOMODALEMO HE!!Awon enia ma nwa lati Ila Orangun, Osogbo, Ibokun, Inisa, Oyan ati gbogbo agbegbe Iree lati wa toro Omo lowo Orisala yi.

Eebo nwon ni igbin mefa ati Eko ati Ekuru tin won yo fi je Eko pelu igbin ati obe egusi.

Nipa igbagbo ti awon enia wonyi ni si Orisa nla yi ni ododo ati otito, o daju pe omo ni Aagan na yio gbe wa dupe ni ajodun orisa ti o tele.

Page 9: Itan nipa awon omo abiola 1

Sugbon ojo ngori ojo, Omo Oba Iree Kan Fe ABENI ni iyawo, ABENI si bi Omo meta fun omo Oba yi.Ni kika, Omobinrin meji ati Omokunrin kan. Obinrin akoko ni oko ni ile Eesa Iree, Omobinrin keji ti won npe ni TENIOLA ni oko ni ile Asalu, sugbon lehin iku Iya Olorisa yi ni omo re Okunrin di Oba ilu Iree.

Oba ilu Iree yi wa ranse si egbon re ti o ni Oko ni Ile Eesa pe ki o wa gbe orisa iya won si odo, sugbon Obinrin yi ko lati gbe orisa si odo nitoripe oko re ko gba fun un lati gbe Orisa iya re sodo.

Lehin na ni Oba Iree yi ranse si egbon re TENIOLA ti o ni oko ni ile Asalu> TENIOLA si gba Orisa nla yi nigbati Oko re re ti gba be fun, inu Oba dun pupo o si gba wipe ohun yo w a ma fi ori bale fun Orisa Iya awon lododun pelu awon Ijoye on ati wipe on yo si ma fi Ake Eran Ewure nla kan ati Oti sekete sago kan sile fun inawo Orisa ti o wa ni idile Asalu lododun.

Page 10: Itan nipa awon omo abiola 1

Idi niyi ti Oba, Ijoye ma nfi njo wa tilu teye wa si ile Asalu ni ilu Iree lododunn. Idi si ni yi ti gbogbo enia ni ilu Iree fi ma nwipe “ORISA ASALU LO NI ILU IREE.”

Idi Pataki Orisa Asalu ni lati ma gbadura ohun rere fun Oba ati gbogbo enia ilu Iree lati Isedale.

AWON OMO ABIOLA L’ANA ATI L’ONI

ORIKI ABIOLA ILE ASALU IREE:Egun anunmi omo oye okaOmo oloponda, omo agan beleOmo agan ko bi duduPupa pupa ni won nbi ninu ile waOmo egun anunmi iyan ko ba oka reIyan abara funfun, oka abara minijoLojo egun anunmi ti daye ko jale riOju oloko nise mu ohun ti yoo je

Page 11: Itan nipa awon omo abiola 1

Won asowo koloboNwon amako ewe elewe jeOmo alu Bembe jake odoOmo ero ti nroke aaree ko ma rinseKo ya ile baba Adebanke ko mesinWon ni nitori kini, awa ni omo AlesinloyeAwa ni omo alesin lekanOmo olowo oke aare kowo sile ko gbodeEgun anumi ara opondaOmo ada roko tan, ada sun gbonran-gandanOmo agan ti je toloO to ori igba gun igba, otori emi b’o ori emiIyan ko b’okare, iyan a bara funfunOka abara minijoOmo Ibadan mesi ogoOmo AlesinloyeOmo atidigun ibakaAbirin esin kutupa-kutupa

Page 12: Itan nipa awon omo abiola 1

Abiola Akande je okan ninu Omo Olohunde Olagunju ni Ile Asalu ilu Iree. Iya re je omo ile Odoka, Oke-Aree ni ilu Iree.

Awon omo iya Abiola Akande ni Akinola Adedeji, Mama Adetola ile Okoro Iree ati mama Opadokun ile Aragbale Iree. Omo Baba Abiola ni Baba ti o bi Samu Orisadare ile Asalu Iree

Abiola ni iyawo meta ni igba aye re ti oruko nwon nje Omikeye ile Oba Iree,. Oruko ekeji ni Pooye lati ile Balogun Gudugba Iree. Eketa sin je Morenike lati ile Pele ni Ilu Iree.

Omikeye ni o bi Fodeke ti o ni oko ni osogbo ati Bola iya Oyerinde ti o ni oko ni ile Alaaru ni ilu Iree

Pooye ni o bi Popoola (Baba Akinade) on na lo si tun bi Mopelola ti o ni oko ni ile Ofele ni ilu Iree

Page 13: Itan nipa awon omo abiola 1

Morenike ni o bi awon omokunrin mefa ti oruko won nje Adewale, Agboola, Adebiyi (Inagije Ojikutu), Olawuyi, Olasinde ati Oladosu.

AWON OMO IDI OMIKEYE ABIOLA NIYI:a. Bola ile Alaaru Iree ni o bi Oyerinde ile Alaaru Ireeb. Fodeke Ile Alubata Osogbo ni o bi Alhaji Ayinde ile Alubata Osogbod. Fodeke na ni o bi Omotoso ile Alaloja ni ilu Iree, on na ni o si bi Jimoh ati supo ile Oba Aagba.

AWON OMO IDI POOYE ABIOLA NIYI:a. Odenike ti o ni oko ni Eripa, Odenike si bi Saratu, Yesufu, Amina, Ayisatu, Humani si ile Bale Eripa

Page 14: Itan nipa awon omo abiola 1

b. Popoola ile asalu ni o bi Akinade Serah ti o ni oko ni ile Alaloja ni oke-ogii ati Abraham popoola abiola. On na ni o bi Rebeka ati Paul ti nwon ku ni omode.d Mopelola ti o ni oko ni ile Ofele je abikanyin Pooye

AWON OMO IDI MORENIKE:I. ADEWALE ni omo akobi Morenike fun Abiola; sugbon o ku ni omode (Shitu Adewale)II. AGBOOLA ni omo Morenike keji (Joseph Alawoki Agboola)

Ti o bi awon omo wonyi:DAVID ADEBAYOJACOB ADEGBOKEZACHEAUS ADELEKEEZEKIEL OLAOSEBIKANAJIBADE ALABIMOSES ADEDOKUN

Page 15: Itan nipa awon omo abiola 1

COMFORT ADERINOLA

SALAMI OYINLOLA ADEBIYI Inagije: OJIKUTU PILE ORO ni o bi - SAKA ADIGUNGANIYU ADENIHUNRAIMI ADEREMIOLAYIWOLA AFOLABILATI ADEGBOYEGAMUDASIRU ADEMOLALAWRENCE MOSHOODBOLANLE A PINLEFALILATU AMOKESILIFATU ARINKESIDIKATURAMOTA ABEJEMULIKATU AYOKAAMINATU APEKE

Page 16: Itan nipa awon omo abiola 1

III. OLAWUYI JONAH AKANGBE – Omo kerin ni o bi:JOHN AFOLABIOLUFEMI ADESINA JOSHUAJOHN AKINTAYOFELICIA OLAWUMI (MRS.)JULIANAH ADEWUNI DAIRO (MRS.)SERAH TITILAYO BAMIJOKO (MRS.)ABIGAEL FOLASADE ASAKE BAMIKOLE (MRS.)MARIA OLAREWAJU (MRS.)RUTH OMOTAYO OJO (MRS.)DORCAS SAJUYIGBE (MRS.)OYINLADE (MRS.)FUNMILAYO OLOWE (MRS.)SAMUEL ADEBISIJOEL GBADEBO

IV. OLASEINDE JOSIAH – Omo karun ni o bi:JANET AYOKA

Page 17: Itan nipa awon omo abiola 1

AYODELE ALAKEAMOS OLUSOLASUNDAY ADEREMIOLADIPO FOLORUNSOTUNDEKOLAWOLEOLUWAGBENGAOLUDAYODAMOLADELE AKINWUMIOLUTOLAJUMOKE OMONIOLAFOLUKEFUNMILOLAATILOLA FUNKEMONISOLA OLAYEMIFUNMILAYOTEMILOLA

Page 18: Itan nipa awon omo abiola 1

V. OLADOSU EMMANUEL – Omo kefa ni o bi:GABRIEL ADEWALEKAYODEOLANREWAJU ADISATOYINTAIYECOMFORT APEKELYDIA ODEEOLUFUNKE

OMOKUNRIN POOYEJAMES POPOOLA ni o bi:AKINADE AMOSABRAHAM AKANJISERAH ABIKEPAULREBECCA

ORIKI OMO AAGAN ILE ASALU, IREE.

Page 19: Itan nipa awon omo abiola 1

OMO AAGANOMO AGAN ORAN TI YAN LOSANOLUGBEGE OMO AAREOMO ERANKO YAYOOMO BA OKO REENI KO NI ISEISE OKO T’OMO JEMEE AGAN

IWOSI OMO ABIOLAOlorun ti o nda enia, o da nwon ni t’akot’abo. O da won ni giga at ni kukuru o si da nwon ni dudu ati pupa.Awon Baba wa so wipe Baba awon tin je Abiola Akande je enia giga, ati wipe awon iyawo re je enia kukuru. Olukowe yi mo Morenike, okan ninu awon iyawo Abiola, o si mo pe enia kukuru ni, Morenike tun pupa feere ninu awo.Awon omo Abiola ndudu, nwon sin pupa, nwon nje enia giga won sin je enia kukuru nitoripe bi omo ko ba jo Baba yo jo iya.

Page 20: Itan nipa awon omo abiola 1

Awon omo Abiola a mo ni ewa pupo, ila mejomejo si ni won nma nko ninu ebi won. Itan Yoruba so pe onimejomejo kii ise eru, omo Oba ni.Idile Abiola ki ise alarun rara, won a mo gbo, nwon a si ma to. Nwon ko ni arun oju, nwon ko si ni arun ara, opolopo won nma di arugbo lati ese, nwon ma nfi oju ati iwa jo ara won.

IDANAAWON NKAN TI A GBA LORI OMO ABIOLA TI O N LO SILE OKO LODE ONI:1. Owo Ori 5,000.002. Owo Baba 2,500.003. Owo Iya 1,500.004. Owo omo ti a nSin f’oko 2,000.005. Owo Omolebi odede 1,000.006. Owo Owe 500.007. Owo adura 500.00

Page 21: Itan nipa awon omo abiola 1

8. Owo Omo-ile 1,000.009. Owo Obinrin-ile 1,000.0010.Owo Omolosu 500.0011.Owo Obinrin Odede 1,000.0012.Owo Omoge ile 1,000.0013.Waini Atunilara(2) 1,000.0014.Orogbo (21) 15.Obi Abata (40)16.Apo Iyo Obe(1)17.Oyin Igo (2)18.Isu (41)19.Matina Kireti (2)20.Apoti Oti Elerindodo (2)21.Eru IyawoISE OMO ABIOLAAgbe ati onisowo ni awon omo Abiola. Nigbati owo-eru ti pari tan. Abiola je onisowo larin Iree ati Ibadan. O ma nta Aawo, o si nta Ewe-taba ati Aso kijipa. O ma nsise Agbe oko. Baba re si ni oko ni Ajiji ni oke odo Aisin, ni

Page 22: Itan nipa awon omo abiola 1

ilu Iree. Ise owo bayi ni iran omo Abiola jogunba ti opolopo won nsi se titi di oni. Loni ewe, opolopo awon omo Abiola nsise Alakowe ni orilede Naijiria ati ni Oke-okun.

OORE-OFE PATAKIOLORUN FUN IDILE Abiola ni oore-ofe Pataki ti ko ye enikeni, notoripe won nma goke ninu isekise ti won bada owo le. Ibase agbe, ibase owo sise, ibase ise alakowe. Oore-ofe yi wa fun idile yi lati iran de iran.

ESINEsin orisa bibo ni esin ibalaye awon Baba wa. Orisa oko ati orisa Asalu si ni Baba wa Abiola Akande ma nbo. Awon omo re ati awon iyawo re na si ma ba boa won orisa wonyi. Sugbon nigbati o ya, Esin imole ati Esin igbagbo de ni odun 1906 ni okan ninu awon omo Abiola (JOSEPH ALAWOKI AGBOOLA) gba esin Kristi onigbagbo ni ilu Iree. Awon aburo re, Jonah Olawuyi, Josaya Olaseinde, James Popoola ati Emmanuel Oladosu si te lee. Ti awon na di Kristieni onigbagbo. Awon omo Abiola k obo

Page 23: Itan nipa awon omo abiola 1

orisa mo loni, die ninu won je imole Musulumi, awon yoku si je elesin Kristi. Shitu Adewale ati Adebiyi Ojikutu gba esin imole.

ODUN TI WON LO NI AYE1. Shitu Adewale 20 years2. Joseph Alawoki 90 years3. Adebiyi Ojikutu 70 years4. Jonah Olawuyi 86 years5. Josiah Lasinde 90 years6. James Popoola 65 years7. Emmanuel Oladosu 93 years

ITAN AYE WON NI SOKISHITU ADEWALE (OMO ABIOLA AKANDE)Shitu Adewale ni akobi omo ti morenike bi fun Abiola Akande. Arakunrin yi ko pe pupo ni aye. O ku ni bi omo ogun odun, leyin igbati o de aye. O je onise aso riran ni ilu Kafancha ni oke oya Ko ti fe iyawo nigba ti o ku.

Page 24: Itan nipa awon omo abiola 1

JOSEPH ALAWOKI AGBOOLA AWEDA OMO ABIOLA AKANDEJoseph Alawoki agboola ni omo keji ti Morenike bi fun Abiola Akande. O lo to aadorun odun ni aye ki o to fi aye sile. Oluko iwe yi mo Papa Joseph Alawoki ni igba aye re gege bi eni ti o feran ebi, ti o si ni suru pupo. Joseph Alawoki jade ni aye ni ojo kejidinlogbon, osu kini odun 1975.Ni igba aye re, Joseph Alawoki je agbe ni oko baba re ni Ajiji, oke-odo aisin, Iree. O fe lati mo iwe ka ati kiko nitori idi eyi, o lo si Abeokuta lati lo sise omo-odo lodo awon oyinbo. Ni asiko yi, Joseph Alawoki agboola ko nipa kika ati kiko iwe ede Yoruba ati ni ede oyinbo pelu. Ni aye igba na, awon oyinbo fe se titi oju irin, won si gba Joseph Alawoki Agboola gege bi okan ninu awon osise won. O je akowe fun awon oyinbo nigbati won nse ise oju irin (Railway line) lati ilu eko lo si ilu Kano. Joseph Alawoki je okan ninu awon osise ti o mu oju to awon osise, ti o nsi nma la ise oju irin ti won yo se fun won.

Page 25: Itan nipa awon omo abiola 1

Nigbati o pada de si ilu Iree lati Eko. Awon enia oke aree ni ilu Iree yan ni ise sekitiri (secretary) fun egbe omo Oke Aree.Joseph Alawoki agboola ati Rev. Omilade ni o ba Oyinbo (District Officer Oyo) soro ni ede oyinbo ni ilu Iree ti oyinbo si fi gba pe ki Post office ki o wa ni ilu Iree, Baba wa yi si ni o sise Postal Agent fun ilu Iree fun odun Mejidinlogun ki agba to de. Ni asiko kan ninu igbesi aye re, Joseph alawoki Agboola je onisowo ti o nma ta ewa eree tutu ati iyere, ti won nfi se iru obe. Ohun si ni baba egbe eleree ni ilu Iree. Baba wa yi feran igbesi aye alaafia nigba aye re, o si ko ireje.

SALAMI ADEBIYI ASUNMO OJIKUTUSalami Adebiyi ni omo keta ti Morenike bi fun Abiola Akande. Oruko ti Baba re so ni Adebiyi, oriki re si ni Asunmo. Ojikutu ni oruko inagije re, inagije yi si di tire nitoripe ki ise ole o si feran ki o ma ji ni kutukutu lati sise.

Page 26: Itan nipa awon omo abiola 1

Oluko iwe yi mo Salami Adebiyi Ojikutu ni igba ti o wa laye. Baba wa yi feran otito ninu ohunkohun, o si ma binu fufu si iro ati eke. O ni ife ti o po pupo fun ebi re nigba gbogbo, ko si ni gba ki enikeni ki o yan ebi re je. Gege bi mo ti so, iyawo mefa ni o ni nigba aye re. iyawo akoko ti oruko re nje Aasia ku laipe ojo lehin igbati o fee. Okan ninu idi niyi ti o fe obinrin mefa. Baba wa yi gbonju si ise oko sise pelu Baba re abiola Akande ni oko Ajiji, nigba ti o ya o bere sise owo. Olorun fi owo sise kee lopolopo. O je gbajumo onisowo ni ilu Iree. O ma nta ewe-taba ati aso kijipa, ti o ma nlo ra ni igbo Ekiti(Ekiti State) ti o si ma nlo ta ni Iwo ati Ibadan, ara awon onisowo re nigbati o wa ni aye ni Daniel Adeoye inagije “Amobiojo” ti o je oye Ojomu ni igba aye re ni ilu Iree. Ojikutu ni o ko ra Moto (Bedford) akero ni ilu Iree.Gege bi onisowo, igba kugba ti Ojikutu at Amobiojo nba lo si Ekiti tabi Ibadan, awon mejeji yo di eru won si oju kan, owo ti Ojikutu yio wa ni Oke eru beni owo ti Amobiojo yio wa ni isale eru won. Idi niyi ti won nfi nma pa owe ni ilu Iree pe “owo Ojikutu oke eru nig be, owo Amobiojo a wa ni isale. Amobiojo a fi

Page 27: Itan nipa awon omo abiola 1

tire je Ojomu.” Ojikutu a ma ta ewe taba, a si ma fi ero-ogi ti o ra lo ogi fun awon enia ilu Iree. O je eniti o feran ile iya re ni ile Pele, Oke-Ogi, Iree pupo. Baba iya re, Lanigan wa lati Ilu Ibadan, ni ile pelu seriki oja Oba Ibadan nitori idi-eyi, igbakigba ti Ojikutu ba lo ta awon oja re ni Ibadan, ile iya Baba re ni o nma de si. Olukowe yi ti baa lo si Ibadan ri. Ojikutu je elesin Musulumi ti o gbajugbaja ni ilu Iree ni igba aye re.Adebiyi Ojikutu lo to aadorin odun ni aye ki o to ku.Eje ki nki Ojikutu ati awon omo iya re si ile iya won:

ORIKI ILE PELEOmo olamiseOmo ikudaruOmo aridi ogo logunOmo aroyin ogun bere f’agbeEmi ko ni s’alo fun eniti ko feran mi

Page 28: Itan nipa awon omo abiola 1

Ojetokun aroti we bi ojoOmo bunibinu bebu wontiriwontiriEla oje ko sunle, o di ori odoOmo agboro muko oyinIkaka ni a mu eko adunOmo elaoje ki jega mama mi niN mase fi weresereMorenike omo Olanigan, omo OlawoyinOmo paja fun won ro awoIbiti mo mo ona deNi ngo sin yin deOjetokun mo pada nibe hunOmo gbowo kari owo na.

JAMES POPOOLA AKANNI(OMO ABIOLA AKANDE)James Popoola je omo Abiola Akande. Iyawo abiola Akande keji to oruko re nje Pooye ni o bii fun. Olukowe yi mo James Popoola ni igba aye re. Baba je oniwatutu enia. O si je eniti o

Page 29: Itan nipa awon omo abiola 1

feran gbogbo ebi Baba re gidigidi, ibiti awon egbon re ban lo ni on ma nlo. Ibikan si nio gbogbo won ma nte si, nigbati won ba ti jo s’oro. O je onigbagbo tokantokan ninu Kristi, Ijo Baptist ni Oke-eesa ni ijo re. papa Popoola ku lehin igbati o ti lo bi Aadorin odun ni aye. Ni igba aye re, os ise (saw Miller) lagilagi pako ni Apomu fun opolopo odun. Nigbati o pada de si ilu re ni Iree, o bere si se owo ati Agbe. Owo ti o se kanyin ni ewe-taba tita ti o si ni owo. O la owo, ko si ni gba ki omode baje. Iyawo meji ni o fe ni igba aye re. oruko akoko fe re ni OMOWE AWERO. Iyawo keji sin je DEBORAH, ti o di iyalode Iree loni.

JONAH OLAWUYI AKANGBE ABIOLA.Jonah Olawuyi Akangbe de aye ni odun 1900. Oruko Baba re ni Abiola Akande eniti a bii ni ile Asalu, Oke Aree, Iree. Oruko momo re ni

Page 30: Itan nipa awon omo abiola 1

Morenike Atoke, eni ti a bi ni ile Pele, oke-ogi, Iree.Jonah Olawuyi Akangbe Abiola jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala re ni odun 1922 gege bi ilana ijo onitebomi. Won se iribomi fun un ni odo Aisin, lati owo oyinbo kan ti oruko re nje Dr. George Green ni odun 1922.Jonah Olawuyi Akangbe je olotito, eniti o se gbokan le nigba aye re, o si fi iwa otito lo igbesi aye re ja. O feran molebi re pupo. Is e owo ti Jonah Olawuyi Akangbe ko lati odo Baba re Abiola Akangbe ni aso kijipa tita. Baba re a mo ran lo si igbo Ekiti ni ilu Otun, Usi, Iyapa, Ayetoro lati lo ra aso kijipa. A situn ma ran an lo si iwo ati Ibadan lati lo taa. Ese ni Jonah Olawuyi Akangbe ati awon onisowo bi tire ni Ilu Iree fi ma nrin lo si awon ilu wonyi nitoripe mooto ko tii po ni oju titi bi ti ode oni. Irin won lati Iree lo si Ibadan ma ngba ojo meta gbako. Awon ore re ni igba aye re ni Daniel Atoyebi, ile Ologbin, Iree, Lawani, Toye, ile Oluode, Isaac Babatunde, Joseph Adeyemo, Joseph Bankole, E. A. Awodiji ati Sunmonu Oyeboade. Iyawo m,eta ni Jonah Olawuyi Akangbe fe ni igba aye re titi won si bi omo fun un.

Page 31: Itan nipa awon omo abiola 1

Oruko awon iyawo naa ni:1. Esther Bolape lati ile Eeesa, oke Eesa, Iree2. Alice Ibisomi lati ile Olokuta, Iree.3. Lydia Adewale lati ile Baba elesin, Oke Aapo, Iree.4. Gege bi eri lati odo awon omo, ebi, Oba ilu ati awon eniyan ti won mo Jonah Olawuyi Akangbe daradara nigbati o wa ni aye, Jonah Olawuyi Akangbe Abiola je eni ti Olorun fun ni ebun ogbon ati oye ninu oro siso. O je onisowo ti o gbaju gbaja ti o si ni owo lowo ni ilu Iree. O feran awon ebi re pupo.

JOSAIH OLASINDE ABIOLAAwon enia ti o mo Abiola Akande so wipe Josaih Olasinde ni o fi wiwo joo ju ninu awon omo ti o bi.Josiah Olasinde de aye ni bi odun 1904. A bi si agbo ile Asalu ni ilu Iree. Iya re ni Morenike Atoke omo ile Pele ni oke ogii, Iree. Inu esin orisa – oko ni won bii sii. Sugbon o gba Jesu

Page 32: Itan nipa awon omo abiola 1

Krisiti gbo ni odun 1918. Ijo onitebomi ni o darapo mo ni ilu Iree.

Inu ise oko ni Baba re bii si o si sise yi fun opolopo odun nigba aye re. arakunrin yi ko feran ise oko pupo, nigbati o si di odun 1927, o kuro ni ilu Iree lo si Offa-kwara Sate lati lo ko ise aso reran. Odun meta ni o fi ko ise aso-riran yi (1927-1930). Lehin igbati o ko ise tan, o duro si ilu Offa lati ma sise ti o ko yi. Ni odun 1933, o fe iyawo re akoko ti a n pe ni Alice Adepele, awon mejeji sib ere si se owo. O si tun fe Dorcas Wuraola omo Erinle si keji. Awon mejeji si bere si se owo.Josiah Lasinde kuro ni Offa lo si Osogbo ni 1948 lati lo s’owo. O s’owo pelu awon United Africa Company ati G. B. Ollivant. Ni odun 1947 ni o fe iyawo keta ti oruko re nje Maria Omowumi, omo ile Elega, Iree. Josiah Lasinde te siwaju ninu esin Kristi ni ilana onitebomi ni Osogbo. Ijo ti o darapo mo ni akoko yi ni First Baptist Church, Oke-Okanla, nigbati osi ya, Josiah Lasinde wa larin awon enia ti o da ijo Union Baptist Church, odi-olowo sile ni Osogbo.

Page 33: Itan nipa awon omo abiola 1

Ni odun 1958, Josiah Olasinde tun fe iyawo miran ti oruko re nje Mary Modupeola, omo ile Lasigun, ni ilu Osogbo. Ni igba aye re, Josiah Lasinde je akikanju onisowo ni Osogbo. O si je gbajumo ati eniti o feran awon ebi re.

EMMANUEL OLADOSU AMAO ABIOLAEmmanuel Oladosu Amao omo Abiola Akande de aye ni odun 1914. Won bi ni ile Asalu ni ilu Iree. Oruko iya re ni Morenike ile Pele, Oke-Ogii ni ilu ire.Oun nikan ni o lo so ile-iwe ninu gbogbo awon omo iya re ati Baba re.O bere ile iwe ni Baptist Day School, oke Aree, Iree ni odun 1923 o si pari ile iwe Primary School re ni 1933.O koko sise akowe fun iwon igba die ni Agbowa-Lagos State, nigbati o si di odun 1933 o pada wa ma gbe odo egbon re Josaih Olasinde ti o n sise ransoranso ni Offa Kwara State.

Page 34: Itan nipa awon omo abiola 1

Ni odun 1942, Emmanuel Oladosu Amao dara po mo ise ologun ti o si ko ise ologun ati ise Nurse. O je okan ninu awon omo ogun Naijiria ti o sise ologun ni Italy (World war II)Nigbati ogun Hitler pari tan ni 1946, o pada wa si ile(Nigeria) o si je okan ninu awon Ajagunfehinti ti o da Nigeria Legion sile ni Osogbo. O gbe iyawo ni odun 1946. Oruko iyawo na ni Elizabeth Taiwo Asande, omo ile Itake, oke-ogi, Iree.Emmanuel Oladosu Amao je olotito enia, eniti o ma nfi gbogbo ara ati okan sise, o si je olufe idile ati gbogbo enia. O feran lati ma ran gbogbo idile lowo. Awon ilu Iree yan an si ipo Councillor ninu ijoba Ifelodun Federal Government ni Ikirun ni asiko ti o ti ogun de, ti o nsi ngbe ilu Iree.Ni odun 1956 ofe iyawo kan si ti oruko re nje Comfort Ayodele omo ile Balogun-gudugba ni ilu Iree. Emmanuel Oladosu Amao da ise ogun oyinbo tita sile ni ilu Iree ati Osogbo ni gba aye re, ise yi si lo se titi ni Osogbo titi o fi kuro ni aye.

Page 35: Itan nipa awon omo abiola 1

AWON OMOBINRIN TI ABIOLA AKANDE BI:

ADEDOYINOruko omobinrin akoko ti Abiola Akande bi ni Adedoyin ; Omikeye ni o sib ii fun.Adedoyin ni oko ni oke-Eesa. O je eniti o feran lati ma sise. Ara ise re ni ogi agbado ni tita. O je olowo o si ni awon iwofa ti o ma nba sise ni ile oko re. abiku daa lamu ko si bi omo Kankan ye, o ni ife awon omo aburo re pelu iyawo won, o si ma nko gbogbo won mo ara. Olukowe yi moo nigbati o walaye.

BOLABola je omo Abiola Akande. Iya re si ni Omikeye. O ni oko ni ile Alaaru ni ilu Ireee. On si ni o bi Oyerinde, Ile Alaaru. Ko pe laye pupo sugbon o ni iwa rere, ti awon aburo re ni idi Baba si nma royin re.

WURAOLA FODEKE

Page 36: Itan nipa awon omo abiola 1

Omikeye na ni o bi Wuraola Fodeke fun Abiola Akande. O je arewa obinrin sugbon ko ni ori oko. Wuraola ni o bi Joel Omotoso si ile Alaloja ni ilu Iree. On na ni o bi Alhaji Ayinde si ile Alubata ni Osogbo. Nigbeyin, o fe Agba gba gubu Odudare ti o je omo Oba Aagba o si bi omo meji si be ti noruko won nje Jimoh ati Olasupo Odudare. Wuraola feran awon omo re ati ebi.

ODENIKEIYAWO Abiola Akande ti a npe ni Pooye ni o bi Odenike. Odenike je obinrin onisuru ati ologbon. Odenike ni oko ni ile Bale, Eripa osi bi awon omo daradara sibe.Oruko awon omo re ni Yesufu, Amina, Ayisatu, Humani ati Saratu. Odenike feran awon ebi re ni ilu Iree gidigidi.

MOPELOLAIYAWO Abiola Akande ti a n pe ni Pooye ni o bi Mumuani Mopelola. Mopelola je arewa

Page 37: Itan nipa awon omo abiola 1

obinrin, o fi jijo ni wiwo jo Josaih Olasinde. Eniyan tutu bi adaba ni Mopelola. Awon egbon re feran re pupo. O ni oko ni ile ofeele ni ilu Iree, o si bi awon omo sibe. Okan ninu awon omo naa ni Alfa Oseni.

AWON IYAWO OMO ABIOLA AKANDE (OWO KEJI)Shitu Adewale – ko ni iyawo. Ko bi omo nitoripe o ku ni kekere

Joseph Alawoki – iyawo meji ni o ni nigbati o wa laye. Awon ni Aina Abebi ti o fe lati ile Dana ni ilu Iree. Ekeji ni Victoria Olayinka Awero ti o fe lati ile iyalode ni Ilu Eripa.

Salami Adebiyi (Ojikutu pile oro) – iyawo mefa ni o fe nigba aye re. Asia ni iyawo re akoko ti o fe lati ile Lemomu, oke ogii, Iree.Aayi Abeegbe ni iyawo re keji ti o fe lati ile Alukoro ni ilu Iree.

Page 38: Itan nipa awon omo abiola 1

Muniratu Alake ni iyawo re keta ti o fe lati ile Ologbin ni ilu Iree.Mopelola Anike ni iyawo re kerin ti o fe lati ile Olorisa oko ni ilu Iree.Olakitike Akanke ni iyawo re karun ti o fe lati ile Omokanola, oke obe ni ilu Iree.Eyinade Arinpe ni iyawo re kefa ti o fe lati ile Oluawo, oke aree, Iree.

Jonah Olawuyi Akangbe – iyawo merin ni o fe nigba aye re. Esther Bolape Amori ni iyawo re Akoko ti o fe lati ile Eesa ni ilu Iree.Ibisomi Esuu ni iyawo re keji ti o fe lati ile Olokuta ni ilu Iree.Lydia Abeo ni iyawo re keta ti o fe lati ile Baba Elesin, oke Aapo ni ilu Iree.Ayii Abegbe ni iyawo re ti o fe ninu opo

Page 39: Itan nipa awon omo abiola 1

Josaih Olasinde – Iyawo marun ni o fe nigba aye re.Alice Adepele Ajini ni iyawo re akofe ti o fe lati ile Lagbedu ni ilu Iree. Dorcas Wuraola ni iyawo keji ti o fe lati ilu Erin-ile, Kwara State.Omowumi Abeo ni iyawo re keta ti o fe lati ile Elega ni ilu Iree.Mopelola Anike ni iyawo kerin ti o fe ninu opo.Mary Dupeola Alake ni iyawo re karun ti o fe lati ile Lasigun ni ilu Osogbo.

Emanuel Oladosu – iyawo meji ni o fe nigba aye re.Taye Asande ni iyawo re akoko ti o fe lati ile Itake, oke ogii, Iree.Comfort Ayodele Agbeke ni iyawo re keji ti o fe lati ile Balogun-gudugba ni ilu Iree.

JAMES POPOOLA – iyawo meji ni o fe nigba aye re.

Page 40: Itan nipa awon omo abiola 1

Omowe ni oruko iyawo re akoko ti o fe lati ilu Eripa.Deborah ni iyawo re keji ti o fe lati oke areee, Iree.

ILEGBE AWON OMO ABIOLA AKANDE

AWON IRANTI MI – Awon iranti mi lo si nkan bi ogota odun sehin. Mo ranti pe gbogbo ilu Iree fe lati oke –aree de ile Oluawo igbogbale, ni ibi odo Aasa. Mo si ranti pe koriko ati ewe gbodogi ni won fib o opolopo ile ni ilu Iree.

Mo ranti pe bi ina ba ti njo ile oke kan, gbogbo enia ni yo tu sita lati wa nkan idena lati pa ina na ki o to se ose fun awon ile miran ni arin igboro.

Aanu omo enia po si ara won, awon enia ki si ma huwa konkojabele.

Page 41: Itan nipa awon omo abiola 1

Mo ranti Oba Oyekanmi ni ilu Iree, mo si ranti Oba Olannite ni ilu pelu, ti won wa ni ori oye. Mo ranti bi Oba Iree se nma wa si ile Asalu ni ododun pelu awon ijoye re tilu tifon lati wa juba fun orisa Asalu. Mo ranti bi gbogbo awon ile Asalu se nma njo ti won si ma nyo lati gba alejo Oba won ati awon Ijoye lekan lododun.

Mo ranti bi awon obinrin se ma nwa si idi orisa asalu ni felifeli owuro pelu kete omi won lori won lati wa gbadura ati lati toro omo ati Alafia lodo orisa asalu ti won gba pe o ni ile Iree. Mo ranti bi Asalu se ma wo aso funfun ati ileke orun funfun ti yo si ma mi saworo si ori awon enia pe adura won yo gba.

Mo ranti pe yiyan oko tabi iyawo ma nwa lati odo obi fun omo ni. Obi yio wo ile, yo wo ona eniti omo won ba fe fe ki won ki o to fi owo sii, mo si ranti pe iyawo gidi ni won ma nfe ni isu ni oka.

Page 42: Itan nipa awon omo abiola 1

Mo ranti gbogbo ilke Asalu, mo si ranti odede Baba mi, ikaa Olohunde.Odede kan soso ni gbogbo ikaa yi ni inu ile kan yipo birikiti, inu ile yi si ni gbogbo omo Olagunju Olohunde ngbe.Erupe ni won fi mo ile na, koriko ati ewe gbodogi ni won si fi bo o

Abileko kokan ni o ni iyara tire, ilekun opon aase ti won dara si ni osi wa ni enu ilekun iyara kokanMo ba Adedeji ti o je okan ninu awon omo iya Abiola Akande ni aye. O n si ni Baale Oke-Aree, ni igba aye re. Inu odede kan yi ni gbogbo wa ngbe. Adedeji si ni Agbalagba ju ti o wa ni odede wa. Gbogbo awa omo Olagunju Olohunde di jo ma nse nkan papo ni, gege bi omo baba kanna. Awon yi ni Abiola, Akinola, Adedeji, ti won je omo iya kanna ati Baba Sadare tio je omo Baba won.

Oko Baba wa Plagunju Olohunde ni a npe ni oko Ajiji. Oko yi ni awon Baba Baba wan da ti

Page 43: Itan nipa awon omo abiola 1

won nfi jeun ti won sin fi nse aye ati igba won.Omi ti idile wan mu ati ti won fi new ni omi odo Ologede ni ile Afunso ati odo aabo ni ile Pele ni ilu Iree.Sugbon ojo ngori ojo, won omo Olohunde npoo si olukaluku si nko ile tire. Idi niyi ti ikaa yi fi tesiwaju ti o fi ni awon ile ti o po larin ile Asalu ati larin ilu Iree.

ILE AWON OMO ABIOLA AKANDE NINU AGBOILEIle merin ototo ni o je ti awon omo Abiola Akande ninu Agbo ile Asalu bayi:1. Agboola ati Ojikutu ni won dijo koi le Akoko, ti ode oni ti gbogbo omo Abiola Akande ngbe tele2. Jonah Olawuyi, Josaih Olasinde ati Emmanuel Oladosu ni won di jo ko ole keji ti o je Petesi, Ode oni. Inu ile yi si ni gbogbo awon aya ati omo won ngbe tele.3. Adebiyi Ojikutu nikan ni o koi le keta ti awon omo ati awon iyawo re ngbe tele.

Page 44: Itan nipa awon omo abiola 1

4. David Adebayo ati Ezekiel Olaosebikan ti won je omo Agboola Alawoki ni o koi le kerin ti awon ati awon iyawo pelu omo won ngbe ninu agbo ile Asa tele.Sugbon loni awon omo Abiola Oladipo Akande ti npo sii. Nwon si ti ko awon ile nla nla ti ode oni, si arin ilu Iree.ORIN EBI OMO ABIOLA AKANDE(LATI INU OORE-OFE OLORUN)

OMO ODODOOFI ‘WA RERE JO MIOMO ODODOOF’IRIN RER JO MI

EGBE: O FI’WA RERE JO MO O FI’RIN RERE JO MI OMO ODODO.

Page 45: Itan nipa awon omo abiola 1

AWORAN1. Aba awon Baba wa ni oko Ajiji2. Olukowe, Oloye John Abiola3. Mosalasi Iyaji, Oke-Aree, Iree ti awon

omo Abiola Akande ngbe josin4. 1st Baptist Church, Oke-Esa, Iree ti

awon omo Abiola Akande ngbe josin5. Aba Ile dana ni oko Ajiji, Iree.6. Aba ile Olukoyi ni Oko Ajiji Iree7. Aba aon omo Abiola, Adedeji ati

Akinola ni oko Ajiji Iree8. Odo agbo ile pele ati ile kike, Iree9. ologede ni ile Afunso, Iree10. Orisa Asa Ile Asalu, Iree (300 years

ago)

Page 46: Itan nipa awon omo abiola 1

11. Ile gbigbe kan ni agbi ile Asalu, Iree12. Ile gbigbe kan ti Adebayo ati Ezekiel

Olaosebikan omo Agboola dijo ko si agbomile Asalu Iree

13. Ile gbigbe kan ti Adebiyi Ojikutu nikan ko ni agbo ile Asalu, Iree

14. Ile ti Jonah Olawuyi, josaih Olasinde at Emmanuel Oladosu ko fun gbigbe ni agbo ile asalu, Iree

15. Oni mejo-mejo ila idile omo Abiola16. Papa Emmanuel oladosu Abiola17. Aworan Af’owo ya, Papa Popoola

Abiola18. Papa Josaih Olasinde Abiola19. Papa Jonah Olawuyi Abiola20. Papa Salami Ojikutu Abiola21. Papa Joseph Alawoki Abiola

Page 47: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 48: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 49: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 50: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 51: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 52: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 53: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 54: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 55: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 56: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 57: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 58: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 59: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 60: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 61: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 62: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 63: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 64: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 65: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 66: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 67: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 68: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 69: Itan nipa awon omo abiola 1
Page 70: Itan nipa awon omo abiola 1