GBÍGBÉ NÍNÚ ÒGO OLÓRUN
Transcript of GBÍGBÉ NÍNÚ ÒGO OLÓRUN
iviii
ORO ISAAJU
“Ki a má maa k? ipej?p? ̀ara wa sil?, g?g? bi à?a aw?n ?lomiiran; ?ugb?n ki a maa gbà
ara ?ni niyanju: p?lup?lu bi ?yin ti rii pe ?j? nì nsunm? etile.” Heb.10:25
Okan lara iyanju ti a gba wa ninu iwe mimo gege bi Kristiani ni lati mase ko ipejopo awon
eniyan mimo sile. Nigba ti awon onigbagbo ninu Kristi ba korajopo nipa ife, igbagbo ati
isokan, awon ise iyanu ati ohun ologo a maa sele: won a maa se iranlowo ati atiileyin fun
ara won (Iwe Owe 27:17; Ise Aposteli 2:45-47); won a maa ru eru omonikeji won
(Gal.6:2), Won yoo pe iwalaaye Olorun sokale saarin won (Orin Dafidi 133) eyi ni die
lara awon ibukun ti o le tibe jade. Ni kukuru, won yoo jo maa dagba soke papo.
Gege bi eya ara Kristi, Olorun ti fun wa ni ekunrere awon ebun emi (Romu 12:4-8; 1
Korinti 12). A gbodo se awari awon ebun wonyii, ki a si maa lo won gege bi a se n fi ara
wa jin fun ise Olorun. Gege bi a ba se n se eyi, ijo Olorun yoo maa gbooro sii yoo si maa
tesiwaju sii. Eleyii wopo laarin awon ijo isaaju. Won je akojopo awon eniyan ti o farajin
fun ise Olorun, lai si imotara-eni-nikan, won si n se igboran pelu erongba lati sin Olorun
lona ti o se itewogba. Olorun rin gidigidi laarin won. Ni Jerusalemu nibi ti ijo naa ti bere ati
ju bee lo pelu, ipa awon Kristiani isaaju farahan lona ti o po gidigidi. Iru ipa yii ni a pe awa
Kristiani lati fihan ninu aye lonii.
Ipade ojule n fun wa ni anfani gege bi onigbagbo lati se ojuse yii. Oore-ofe ti Olorun fun
wa leyo eni kookan gege bi Kristiani ko gbodo sofo tabi je asan. A gbodo lo o lati mu
elese wa sinu igbagbo ninu Kristi ati fun imugbooro ijo ati fun idagbasoke enikookan wa.
Iwe yii ti akori re je “GBIGBE NINU OGO OLORUN APA KEJI” ni a gbe kale lati sowaji lati
le tubo fi ara wa jin, ki a si tubo wulo fun ise Olorun , ni pataki gege bi a ti rii pe ojo ipadabo
Kristi leekeji sun mo etile.
Mo dupe lowo Olorun fun gbogbo awon onkowe yii. Olorun yoo bukun yin lopolopo ni
oruko Jesu.
Eyin ara mi olufe, e je ki a fi ara wa han gege bi omo ipade ojule ti o duro sinsin, mo si gba
Olorun gbo pe yoo lo yin fun idagbasoke awon ipade ojule wa.
Alabukun-fun ni yin.
Rev. Sam Aboyeji
Alaboju Gbogbogboo
Ijo onihinrere kikun ni Naijiria
IWE ILANA IKONI FUN IPADE OJULE
Eto Atunko ©2021 lati owo Eka Ikoni Lekoo Kristiani,
Eko, Naijiria
OLUSETO ILANA EKOIVIENAGBOR STEPHEN
ALASE ILANA EKO KAFILAT O. AYANBANJO
AWON ONKOWE
Akibo, Tobi Ivienagbo, Steve Omowo, Funso Sonubi, Wale Chukwutem, Chukuka Ofuani, GabrielAzuka-Obieke, Uche Akinkugbe, Abiola Oyediran, Tunde Olufemi, SeyiOgianyo, Moses Itombra-Okoro JoneCampbell Seyi
AWON OLUYEWEWOAmos Ajayi 'Lara Adediji
OLUTUMO EKO SI EDE YORUBAOlusoagutan (Aya) Akinjogbin Opeyemi
Gbogbo iwe mimo ti a toka si je ti eda oba Jakobu ati awon eda miiran.
A se atejade re lati owoEKA IKONI LEKOO KRISTIANI
Foursquare Gospel Church ni Naijiria,38, Akinwunmi Street, Alagomeji, Yaba, Lagos.
P.O. Box 273, Sabo – Yaba, Lagos, Nigeria
[email protected] or [email protected]
0803 488 0927
ALAYE LORI LILO IWE YII
Ipade ojule kii se ipade ijosin miiran; bee si ni kii se ipade eko Bibeli tabi ile eko ojo isinmi
miiran. O je egbe kekere lara ijo ti o wa fun sisunmo ati ajosepo fun idapo tooto.
Nitori idi eyi, a ti seto iwe naa lona ti gbogbo eniyan ti o wa ni ipade naa yoo fi kopa nibe.
Akiyesi:
Adari ipade ojule gbodo koko se alaye ranpe lori koko eko fun ojo kookan. Gbogbo awon
ti o wa ni ipade ni o gbodo gbiyanju lati dahun awon ibeere fun agbeyewo eko, ki won si
ko idahun won sile (iba dara bi won ba le se akosile re sinu iwe fun idanilekoo yii) Ki
gbogbo awon ti o wa ni ipade wa inu iwe mimo papo(fun awon ese Bibeli ti a toka si) lati
wa idahun si awon ibeere fun agbeyewo eko.
Ninu eko kookan, atona ti wa nibe. Sibe, bi o tile je pe ona ti a oo lo le yato lati ojule kan si
omiran, sugbon ohun ti eko kookan wa fun gbodo fi idi mule. Oludari ipade ojule gbodo
pese awon eniyan ipade sile fun eko ti o n bo, ki o rii pe gbogbo eniyan ni o n kopa nibe.
Ipade igbaradi gbodo maa wa fun awon oluko lati igba de igba, o le je loseese, pelu
aladari gbogbogboo fun ipade ojule. Gbogbo isoro ti a ba n dojuko ni a oo se atojo re, ki a
si ko won fun alakoso idanileko kristiani fun iranlowo ti o ye nipase alabojuto ipade ojule.
viv
ORO AKOSO
Ogo ni fun Olorun fun odun miiran ninu ipejopo ipade ojule wa. Oore-ofe ati aanu Re to
fun wa ni awon odun ti a ti lo koja. A ni igboya wipe Olorun ti o bere ise rere ninu wa je
olooto, yoo ran wa lowo titi de opin. Mo ki wa kaabo si odun tuntun ti o logo ti Olorun yoo
si ba wa pade ninu re. Ki Olorun jowo fi ogo Re han lori wa, ki O si se ohun gbogbo ti o n
se tiwa ni asepe ni oruko Jesu alailediyele.
“Ipade Ojule” wa ti n gbile si I, o si ti n fi gbongbo mule si i. Kokoro fairoosi korona
“Corona Virus” ti o seni laanu pe o tan kaakiri agbaye ati isemole ti ijoba kede nitori re ti
tubo la wa loju si awon anfani miiran fun ipade ojule. Oro aje gbogbo agbaye ni o doju
dele, ti gbogbo ibi igbafe ati awon ile ijosin gbogbo si di titi, “ipade ojule” nikan ni ko kan.
Iwulo ati pataki “ipade ojule” ko see fowo ro seyin. Ninu ohun ti o ti wa di “igbe aye
tuntun” naa, “Ipade ojule” wa ni ibi kan soso ti a ti n pade. Isesi ti emi ati idapo awon
onigbagbo n waye, o si fese mule nipa eto ipade ojule. Iwa mimo fun idagbasoke ninu
emi ati irepo ti ara naa ri aaye fese mule.
Nitori naa, mo ro wa, mo si be wa tokantokan pe ki a mu oro ipade ojule wa ni
okunkundun, nitori ere ati anfani pupo wa ninu re fun wa.
Akori ti odun yii ni “Gbigbe ninu Ogo Olorun”- Apa keji. O je itesiwaju akori ti a beere ni
abala keji odun ti o koja. Olorun pe wa si idapo ki a le ni iriri ogo Re. Olorun da wa fun
ogo Re, O fe ki a maa rin ni yiye niwaju Re, ki a si maa fi ogo Re han ni gbogbo ayika wa.
Bi a ba se n ni idapo papo, ogo Olorun gbodo maa tan ninu aye wa. Awon eniyan ti o yi
wa ka gbodo maa ri, ki won si da iwalaaye Olorun mo laarin wa. A gbodo fi eri miiran lele
gege bi awon onigbagbo ti Antioku (Ise Aposteli 11:17). Nitori naa, e je ki a maa se
afihan ogo Olorun ni awon agbegbe wa gege bi iyo ati imole aye.
Ni akotan, gege bi a se n ko ara wa jo ni awon ibi ipade ojule wa, e je ki a nii lokan pe iko
Kristi ni a je, a si gbodo maa fi iyin Olorun ti o pe wa kuro ninu okun sinu imole Re han. A
gbodo maa fi ogo Re han. Ki Olorun jowo tubo maa fun wa ni okun, igboya ati oore-ofe ti
a nilo lati le se eyi.
Alaafia!
Rev. (Mrs.) K. O. Ayanbanjo
Alakoso Fun Eka Ikoni Lekoo Kristiani
viiivii
IDI FUN IPADE OJULE
Lati le je ipejopo kekere fun afihan ife ati iranlowo fun ara wa.
Lati ko awon eniyan ati lati fun won ni anfani fun ise isin ati lati le so eso
Lati fidi awon ti a jere okan won mule, lati mu won ni ore ati lati faye gba pipo si
i ni iye
Lati faye gba idapo ti o danmoran laarin awon ara
Lati le ran ijo lowo ni sise iranlowo fun awon omo ijo ati awon ti kii se omo ijo
paapaa.
APEERE ALAKALE ETO IPADE
Ipade ojule je eto wakati kan pere. A oo pin wakati naa si wewe bayii:
- Adura Ibeere Iseju Marun
- Orin Iyin Iseju Mejo
- Eko/Iforowero Ogbon iseju
- Alaye lori ohunkokun Iseju marun
- Owo ore Iseju Marun
- Adura ati oore-ofe Iseju Meje
AKIYESI
1. Ipade ojule maa n waye lojoojo isinmi fun wakati kan pere.
2. Ipade ojule n beere lagogo mefa irole, o si n pari lagogo meje irole.
3. A ko gbodo fagi le ipade ojule fun awon eto miiran
4. A ro awon ti o wa ni ipade ojule kookan lati maa lo waasu, se abewo ati lati lo ki
awon ara adugbo won, lati pe won wa si ipade ojule ni aago marun-un irole ki
ipade to bere.
xix
ATE FUN AKOONU
Eko Kinni Ni imo nipa awon ohun ti Emi
Eko Keji Yera Fun Igbojege
Eko Keta Takete si iborisa
Eko Kerin Kun fun Emi Olorun nigba gbogbo
Eko Karun Se ipinnu lati gbe igbe aye iwa-bi-Olorun
Eko Kefa Ni Suuru
Eko Keje Fi Ese-mule ninu Kristi
Eko Kejo Je olooto si awon Adari Ijo
Eko Kesan-an Maa se deedee ni ipade Ijo
Eko Kewa Je Olooto si awon ti o ga ju o
Eko Kokanla Setan lati jiya fun Kristi
Eko Kejila Je Alailetan ninu ise re gbogbo
Eko Ketala Duro sinsin ninu igbagbo
Eko Kerinla Ke pe Olorun Fun iranlowo
Eko Karundinlogun Ya ara re si mimo nipa aawe gbigba
Eko Kerindinlogun Beeere fun awon ileri Olorun
Eko Ketadinlogun Maa gbe iwaju Olorun
Eko Kejidinlogun Isokan ninu Ebi ti Olorun n gbe
Eko Kokandinlogun Rinrin Ninu Ife
Eko Ogun Idariji ati Ija pipari ninu igbeyawo
Eko Kokanlelogun Ebi ti o kun fun Emi
Eko Kejilelogun Teramo iwa-tito ninu ebi
Eko Ketalelogun Yago Fun Igberaga
Eko Kerinlelogun Gbe okan re kuro ninu koseese
Eko Karundinlogbon Mase kegbe buburu
Eko Kerindinlogbon Di oku si Eran Ara
Eko Ketadinlogbon Maa se rere nigba gbogbo
Eko Kejidinlogbon Maa lo agbara ti emi
Eko Kokandinlogbon Se Afarawe Kristi ninu ise alaimotara-eni-nikan
Jan. 3
Jan. 10
Jan. 17
Jan. 24
Jan. 31
Feb. 7
Feb. 14
Feb. 21
Feb. 28
Mar. 7
Feb. 14
Feb. 21
Feb. 28
April 4
April 11
April 18
April 25
May 2
May 9
May 16
May 23
May 30
June 6
June 13
June 20
June 27
July 4
July 11
July 18
July 25
Aug. 1
Aug. 8
Aug. 15
Aug. 22
Aug. 29
Sept. 5
Sept. 12
Sept. 19
Sept. 26
Oct. 3
Oct. 10
Oct. 17
Oct. 24
Oct. 31
Nov. 7
Nov. 14
Nov. 21
Nov. 28
Dec. 5
Dec. 12
Dec. 19
Dec. 26
Eko Ogbon APEJO
Eko Kokanlelogbon Fokan si Titan Ihinrere kale
Eko Kejilelogbon Maa to Jesu leyin pelu Ifaraji
Eko Kokanlelogoji Maa Gbe Igbe Aye ti o ni Itumo
Eko Kejilelogoji Bori Idanwo
Eko Ketalelogoji Fi Awon Ohun Ti Ijoba Orun Se Aayo
Eko Kerinlelogoji Ko Lati Tera Mo Oro Ota
Eko Karundinlaadota Ipolongo Ajo Apapo Ni Agbegbe wa
Eko Kerindinlaadota Funrungbin Sinu Ogba-Ajara Olorun
Eko Ketadinlaadota Yago Fun Aigbagbo
Eko Kejidinlaadota Faramo Otito
Eko Kokandinlaadota Jowo Ohun Gbogbo Fun Olorun
Eko Aadota Sin Olorun Tokantokan
Eko Kokanlelaadota Gba Isakoso Lori Ohun Gbogbo
Eko Kejilelaadota Maa Rin Ninu Emi Nigba Gbogbo
Eko Ketalelogbon Je Eni ti o Lawo
Eko Kerinlelogbon Dagba Ninu Ogbon
Eko Karundinlogoji Fun Olorun ni ohun ti o dara julo
Eko Kerindinlogoji Mo awon Oluranlowo Ayanmo
Eko Ketadinlogoji Ri wipe Emi re wa ni Ilera
Eko Kejidinlogoji Feran Otito
Eko Kokandinlogoji Ajo Apapo 2021: Ipa Tire
Eko Ogoji Maa Gbe Nipa Igbagbo